International News - A Yoruba Perspective

From BBC


Kókó ọ̀rọ̀ tí Alaafin Oyo tuntun sọ l'ọdun Ìtúnu Àwé lẹ́yìn tó dé Adé Sango tán ní Koso
Alaafin Owoade to gba ade Sango ni Koso lọjọ Abamẹta ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta niluu Oyo sọrọ yii ninu ọrọ ikini ku ọdun to fi ranṣẹ sawọn musulumi to n ṣe ọdun itunu awẹ.

Abẹ̀sẹ́kùbíòjò ọmọ Nàìjíríà Olanrewaju ṣubú lulẹ̀ lásìkò tó ń jà lọ́wọ́, ó sì jáde láyé
Fidio ija Olanrewaju ati Mbanugu ti a ri lori itakun ayelujara fi idi rẹ mulẹ wi pe oun gan an lo n lewaju pẹlu ami ayo to pọju ninu ija ọhun ki o to ṣubu lulẹ.

Wo àwọn nǹkaan mẹ́wàá tó yẹ láti ṣe lọ́jọ́ ọdún Eid-el-fitr
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Islam ṣe là á kalẹ̀, àwọn mùsùlùmí gbọdọ̀ ṣe nǹkan mẹ́wàá yìí lọ́jọ́ ọdún láti mú kí ọdún dùn fún wọn.

Ìjíròrò láti dáwọ́ oogun dúró láàárín Israel àti Hamas tún gbérasọ
Ìgbésẹ̀ ọ̀tun yìí yóò pèsè fún Hamas láti tú àwọn èèyàn Israel márùn-ún tó wà ní àhámọ́ wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì máa sinmi oogun fún àádọ́ta ọjọ́.

Ilẹ̀ rírì tó wáyé ní Myanmar ti gbẹ̀mí èèyàn 1,600
Ọ̀pọ̀ àwọn tí ilẹ̀ rírì ṣàkóbá fún ni kò rí ọ̀nà láti àwọn ohun èlò ìrànwọ́ tí wọ́n pèsè fún wọn bí ilẹ̀ rírì náà ṣe ti ba ọ̀pọ̀ ọ̀nà àti ohun améyédẹrùn jẹ́.

Aláàfin Oyo tuntun Ọba Akeem Owoade dé Adé Sango ní Koso, ìlú Oyo mì tìtì
Eyi waye lẹyin ti Kabiyesi Owoade kuro ni Ipebi lọjọ Ẹti ọjọ kejidinlọgbọn oṣu yii nibi ti ori-ade naa ti wa fun bii ọjọ mọkanlelogun.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò, dúkìá bàjẹ́ níbi ìjà ilẹ̀ láàrin ìlú Osi àti Epe Opin ní ìpínlẹ̀ Kwara
Laasigbo naa bẹrẹ ni Ọjọbọ ọsẹ yii, eyi to si yọri si iku tẹgbọn taburo ọmọ iya kan naa ti wọn jẹ ọmọbibi ilu Osi.

''Ìgbà tí mo ti jẹ ọba, ni àwọn obìnrin tó fẹ́ ẹ́ fẹ́ mi ti pọ̀ si nítorí ẹwà mi''
Laipẹ yii ni Ọba Olusola Osolo, di gbajugbaja lori ayelujara, deebi pe , wọn fun ni inagijẹ Kabsbaby

Ojú máa ń tì mí, àwọn ọ̀rẹ́ máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí ọyàn kan ni mo ní - Titilope tó lárùn 'Poland syndrome'
Ajọ NIH to n ri si ọrọ eto ilera sọ pe ''Poland syndrome'' jẹ arun kan ti ko wọpọ to maa n ṣẹlẹ si ọmọ ninu oyun.

Taa ni Aisha Achimugu, gbajúmọ̀ oníṣòwò, tí EFCC kéde pé òun ń wá?
Àtẹ̀jáde kan tí àjọ náà fi sórí ìkànnì ayélujára wọn lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta ni wọ́n ti kéde pé àwọn ń wá obìnrin náà fẹ́sùn lílẹ̀dí àpòpọ̀ láti hùwà ọ̀daràn àti kíkó owó ìlú lọ sí ilẹ̀ òkèrè.

Aráàlú dáná sun àwọn arìnrìnàjò nípìnlẹ̀ Edo, èèyàn méje kú
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, wọ́n ní àwọn èèyàn tí wọ́n pa ọ̀hún ń ṣe ìrìnàjò lọ ní òpópónà Uromi sí Obajana nígbà táwọn fijilanté ìlú Uromi dá wọn dúró láti ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀ wọn.

Ọ̀rọ̀ ìwúrí tí Florence Ajimobi sọ láyàájọ́ ọjọ́ ìbí ọmọ rẹ Abisola, kó tó ò kú lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì
Iya Bisola ko mọ pe gudugbẹ yoo ja lẹyin ọjọ diẹ to n ki ọmọ rẹ kuu ayẹyẹ ọjọọbi pẹlu ọpọlọpọ adura.

Darapọ̀ mọ́ wa lórí WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ

Aláàfin Oyo tuntun jáde ní Ìpèbí lẹ́yìn ọjọ́ bíì mọ́kànlélógún, ariwo sọ l'Oyo
Ọjọ Ẹti ọjọ keje oṣu Kẹta yii ni kabiyesi Owoade wọ Ipebi.

Mọ̀ nípa àbá òfin ọjọ́ orí olùdíje ààrẹ Nàìjíríà, ìdájọ́ ikú àtàwọn míì tí ilé aṣòfin l'Abuja ń gbé yẹ̀wò
Awọn ọmọ ile aṣoju-ṣofin n gbero lati ṣe ayipada abala 131 ati 177 ninu iwe ofin orilẹede Naijiria eyi to sọ nipa ọjọ ori ti ẹni to ba fẹ dije fun ipo gomina tabi ipo aarẹ ni Naijiria gbọdọ to.

"Ọkùnrin mẹ́rin sí márùn-ún ni mo ń wọ́ ara fún lójúmọ́, àwọn míràn sì máà ń bèèrè ‘ìtura’ lẹ́yìn ara wíwọ́"
BBC Yorùbá bá Damilola Apena, tó ń ṣiṣẹ́ ara wíwọ́ sọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ naa, ìpèníjà tó wà nídìí iṣẹ́ náà àti ìdí tó ṣe yan iṣẹ́ ara wíwọ́ láàyò.

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nipa Abisola, ọmọbìnrin Gómìnà Abiola Ajimobi, tó jáde l'áyé
Laaarọ Ọjọbọ ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹta yii ni iroyin iku Abisola Kola-Daisi, jade si ori ayelujara.

Makinde yí ẹnu padà lórí ilé-ẹjọ́ Sharia nípìnlẹ̀ Oyo, ó sọ ìhà tó kọ sí i báyìí
MURIC sọ fun BBC Yoruba wi pe ''a o kuku nija pẹlu ijọba, ohun ta n beere naa ni ẹtọ, ki wọn ṣe deede fun Musulumi ati Kristẹni.''

Kò sí ohun tó ń jẹ́ ìgbìmọ̀ Sharia lábẹ́ òfin Nàìjíríà, ohun tí òfin sọ rèé – Amòfin
Amòfin Effiong sọ pé ilé ẹjọ́ Sharia àti ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Sharia nìkan ni òfin Nàìjíríà fi ààyè gba báyìí tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń lò wọ́n.

Àwọn ànfààní tó wà nínú àjọ SWDC tí Tinubu ṣèṣẹ̀ buwọ́lu ìdásílẹ̀ rẹ̀ fún ilẹ̀ Yorùbá
Ajọ SWDC wa fun idagbasoke awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba nipa ṣiṣe oniruuru akanṣe iṣẹ kaakiri ẹkun naa.

Ẹbí dáwọ́ lu ìyàwó oníyàwó lálùbami nítorí ó kọ̀ láti bu ìyẹ̀pẹ̀ sí òkú ọkọ rẹ̀ àtijọ́
Iṣẹlẹ naa waye ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹta ọdun 2025.

O wà nínú ewu láti ní oyún ìju, tí ìyá, ẹgbọ́n tàbí àbúrò rẹ bá ní i
Awọn nnkan to n fa oyun iju fun awọn obinrin ni Naijiria ati ọna abayọ

Ìjà parí, Pasuma àti Taye Currency parí aáwọ̀ tó wà láàárín wọn
Nínú fídíò kan tí Taye Currency fi sójú òpó Facebook rẹ̀ tó sì ti gba orí ayélujára ṣàfihàn rẹ̀ pé àwọn àgbà olórin náà pàdé ní ìlú Saudi Arabia níbi tí wọ́n ti lọ ṣe Umurah ọdún yìí.

Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ọkọ̀ ojú omi àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tó rì sínú Òkun Pupa
Olu ileeṣẹ orilẹede Russia to wà ni Egypt salaye ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ pe ero marundinlaadọta lo wa ninu ọkọ oju omi naa táwọn ọmọde si wa ninu wọn pẹlu.

Ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì mẹ́rin tó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí Akpabio ti di ààrẹ ilé aṣòfin àgbà l'Abuja
Irufẹ iṣẹlẹ yii tun waye lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹta yii lasiko ti ijokoo igbimọ ile lori ẹsun iyọnilẹnu fun ibalopọ ti Sẹnẹtọ Natasha Akpoti-Uduaghan fi kan Akpabio n lọ lọwọ.

Èèyàn 24 kú nínú ìjàmbá iná tó tíì l'ágbara jù ní South Korea
Ijọba orilẹede South Korea fidi rẹ mulẹ wi pe eeyan mejila lo wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ ọrun latari ijamba ina ọhun.

Wo nnkan tí iye ìgbà tí ò ń ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ ń sọ nípa ìlera rẹ
Ṣáájú àsìkò yìí, onírúurú àwọn ìgbàgbọ́ ló wà nípa iye ìgbà tó yẹ kí èèyàn yàgbẹ́ lójúmọ́ tàbí lọ́sẹ̀ àmọ́ ìwádìí àwọn onímọ̀ bíi Ken Heaton, onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó ní Bristol Royal Infirmary, UK ṣàfihàn pé iye ìgbà tí èèyàn ple yàgbẹ́ yàtọ̀ síra.

'Àwọn darandaran ti lé wa kúrò l'óko, kò dín ní èèyàn méjì tí wọ́n n pa l'ọ́sẹ̀'
Awọn olugbe ilu Ala, ijọba ibilẹ Akure North nipinlẹ Ondo ba BBC Yoruba sọrọ lori ipenija wọn pẹlu eto aabo.

'Ẹkún gbọ̀n mí, ayọ̀ tún kún inú mi lásìkò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi dá ẹ̀bùn fún mi'
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti BBC Yoruba ṣe pẹlu olukọ naa, Ọgbẹni Ezekiel Olagunju, lo ti sọ pe ko si aṣiri meji ninu ibaṣepọ oun pẹlu awọn akẹkọọ naa, ju pe oun mu wọn gẹgẹ bi ọmọ.

Àsìkò òjò la wà yìí, wo bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrá
Ara lo sọ ina le orule ile ẹkọ lori to fi jo .

Ojú dúdú, ẹsẹ̀ funfun - Ẹ wo nnkan tó mú ìyá ọlọ́mọ́ mẹ́fà bóra fún gbogbo ọmọ rẹ̀
Nibi tọrọ naa de duro bayii, Fatimo loun n kabaamọ igbesẹ ara bibo toun gbe naa, nitori aburu to ṣe lara awọn ọmọ oun.

Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ n'Ibadan, 17 dèrò àtìmọ́lé
Mẹtadinlogun ninu awọn akẹkọọ naa lọ wa ni ahamo ileeṣẹ olopaa nipinlẹ Oyo ti wọn yoo si f'oju ba ile ẹjọ laipe

''Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé èmi nìkan ni akẹ́kọ̀ọ́ tó dá wà ní kíláàsì láti 100l dé 400l''
Mojoyinoluwa, akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣìrò tó dá wà ní kíláàsì láti 100l dé 400l

Kojú ọ̀wọ́ngógó pẹ̀lú àwọn oúnjẹ aṣaralóòre yìí tí owó wọn kò wọ́n rárá
Bí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ṣe ń lékún ní gbogbo ìgbà tí owó tó ń wọlé fún èèyàn kò sì lékún jẹ́ kí ó ṣòro láti máa rí àwọn oúnjẹ tó dára jẹ.

Dupe Jayesinmi, oṣere tiata, fomijé ṣàlàyé ìdí tí kò ṣe lọ́mọ láyé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún
Ko sẹni to mọ ibi ti bata ti n ta iya to ti le lọgọta ọdun (60) naa lẹsẹ, afi nigba to fi omije ṣalaye ibanujẹ rẹ nipa aibimọ ati awọn iṣoro mi-in.

HUMILITASCharleans' Contribution Worldwide

300

Charlean Doctors

250

Charlean Engineers

150

Charlean Lawyers

109

Charlean Professors

We always perform at our best when we work together

Our mission is to provide the means & technical know-how to accomplish the aforementioned with HUMILITAS - always