Ètò sínsin ilẹ̀ baba ẹni wáyé lọ́dún 1973 ní ìrètí láti mú ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà nípa gbígbé èèyàn lọ sí ìpínlẹ̀ tó jìnà sí agbègbè rẹ̀.
Nigba to n sọrọ nipa awọn ijiya to wa fawọn to ba kọ lati sanwo ori, alaga igbimọ to n pawo wọle fun ijoba nipinlẹ Oyo sọ pe iwa ọdaran lẹni ti ko san owo ori n hu labẹ ofin.
Ní aago mẹ́sàn-án alaalẹ́ ni àwọn èèyàn máa ń lu abọ àti pọ́ọ̀tì wọn, ní ìdáhùn sí ìpè Mondlane pé àwọn kò faramọ́ kí ìṣèjọba ẹgbẹ́ òṣèlú Frelimo tún tẹ̀síwájú.
Àwọn adájọ́ náà ní àwọn ní ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn èèyàn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn tó ń lọ lórí ogún tó ń wáyé láàárín Israel àti Gaza.
Awọn nnkan jijẹ, ohun lilo bii ina ọba, itọju ailera, eto ẹkọ, sisan owo ile, lilo foonu ati bẹẹ bẹẹ lọ ti di iṣọro bayii nitori atunto ti iṣakoso Aarẹ Tinubu gunle.
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní ìdá mẹ́ẹ̀dógún péré nínú àwọn ìdọ̀tí tó wà káàkiri àgbáyé ni wọ́n ń ṣe àtúnlò rẹ̀ àti pé ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ló máa ń wá ọ̀nà ẹ̀bùrú láti fi da àwọn ilẹ̀ wọn nù.
Ni oṣu kinni, ọfisi ajọ isọkan agbaye gbe atẹjade kan sita lori oju ọjọ ati irinna awọn eeyan, ṣalaye ti igbesẹ ko ba waye, o ṣeese ki ilẹ riri waye ni ọdun 2050.
Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè kẹta nílẹ̀ Áfíríkà, lẹ́yìn Rwanda àti Democratic Republic of Congo (DR Congo), tí yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ ajẹsára Monkeypox.