Nigba to n sọrọ ninu fọnran kan to fi lede loju opo Facebook rẹ, Imaamu Ayilara ni ''a bẹ baba pe ki wọn ma binu gbogbo ohun ti a ba ṣe si wọn gẹgẹ bi ọmọ.''
Ọjọ Aje, ọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun yii ni Alaafin gba ọpa aṣẹ ati iwe ẹri ifinijọye l'ọwọ Gomina Ṣeyi Makinde ni ọfisi rẹ to n bẹ ni agbegbe Agodi niluu Ibadan.
Hamaz kọlu Israel lọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023, nibi ti wọn ti pa eeyan ẹgbẹrun kan le ni igba, ti wọn si ko eeyan igba ati mọkanlelaadọta mii si igbekun.
Lateef Adedimeji tawọn n wo ere rẹ 'Lisabi' lọwọ bayii lori Netflix sọ pe ara awọn ipenija tawọn to jẹ ilumọọka lẹnu iṣẹ maa n koju ni ọrọ tawọn eeyan n sọ nipa ẹbi oun.
SP Rahman Nansel to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa fidi rẹ múlẹ pe awọn ri ẹya ara Salome ti Timileyin Ajayi ti ge wẹlẹwẹlẹ gba lọwọ rẹ nigba tawọn eeyan n lu u lalubami.
Ṣaaju ni fọnran kan ti kọkọ lu ori ayelujara pa eyi to ṣafihan bi Dami ti n ṣe adura fun Portable, ti wọn si jọ n sọrọ lori ati pada Dami sọdọ Portable.
Agbenusọ ọlọ́pàá Ogun, Omolola Odutola, ṣàlàyé pé lálẹ́ Ọjọ́bọ̀ làwọn ajínigbé kan jí ìyàwó ọ̀gá ọlọ́pàá náà gbé nígbà tó ń wọ ilé rẹ̀ tó wà ní òpópónà Aminu Street, Orange Estate, Arepo ní ìjọba ìbílẹ̀ Obafemi Owode.
Trump ti kede pe lara awọn eto toun yoo ṣiṣẹ le lori loni ọjọ Aje ogunjọ oṣu Kinni ni ọrọ awọn eeyan to n wọ orilẹede Amẹrika lọna aitọ, ọrọ oju ọjọ, ofin lori oyun siṣẹ atawọn eto mii.
Ajọ NAHCON ti wa kede pe ọjọ karun un oṣu Keji ọdun yii ni gbedeke fun sisan owo Hajj ọdun 2025, bi bẹẹ kọọ, ẹnikẹni ti ko ba sanwo tiẹ titi ọjọ yii yoo ni lati duro di ọdun 2026 fun iṣẹ Hajj rẹ.
Bi Olabode Thomas ko tilẹ dagba tabi darugbo ko to jade laye, nitori ko lo ju ọdun mẹrinlelọgbọn lọ, to fi tẹri gbasọ, sibẹ a ko gbọdọ gbagbe akanda ọmọ Yoruba yii, tori ipa to ko si idagbasoke iran Yoruba ati Naijiria lapapọ.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdílógún, oṣù Kìíní ọdún 2025 ni àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò lábẹ́nú ní ìpínlẹ̀ Ondo, Ondo State Independent Electoral Commission, ODIEC mú fún ètò ìdìbò láti fi yan àwọn alága àti káhúnsílọ̀ sáwọn ìjọba ìbílẹ̀.
Adari eto iroyin ati ipolongo lẹgbẹ Oṣelu PDP nipinlẹ Ondo Leye Igbagbo sọ pe wọn yan lati ma kopa nitori ajọ to n bojuto eto idibo nipinlẹ Ondo ODIEC yoo ṣegbe lẹyin ẹgbẹ Oṣelu APC ninu eto naa.
We have put an assorted mix of pics here for your enjoyment. We are always hungry for more - so if you have taken or have
access to some pics remotely related to our issue, please do not hesitate to send them to the web admin team